Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 24:46-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

46. “Kíákíá ni ó sọ ìkòkò rẹ̀ kalẹ̀ láti èjìká rẹ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mu ún, èmi yóò sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹ̀lú.’ Mo sì mu, ó sì tún fún àwọn ràkúnmí mi mu pẹ̀lú.

47. “Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘ọmọ ta ní ìwọ í ṣe?’“Ó sì wí fún mi pé, ‘ọmọbìnrin Bétúélì tí í ṣe ọmọ Náhórì ni òun, Mílíkà sì ni ìyá òun.’“Nígbà náà ni mo fi òrùka náà bọ imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà-ọwọ́ náà si ní ọwọ́.

48. Mo sì wólẹ̀ mo sì sin Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa à mi, ẹni tí ó ṣe amọ̀nà mi láti rí ọmọ ọmọ arákùnrin olúwa mi, mú wá fún ọmọ rẹ̀ (Ísáákì).

49. Ǹjẹ́ nísin yìí bí ẹ̀yin yóò bá fi inú rere àti òtítọ́ bá olúwa mi lò, ẹ sọ fún mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹ sọ fún mi, kí ó le è mọ ọ̀nà tí èmi yóò yà sí.”

50. Lábánì àti Bétúélì sì dáhùn pé, “Lọ́dọ̀ Olúwa ni èyi ti wá, nítorí náà àwa kò le sọ rere tàbí búburú fún ọ.

51. Rèbékà nìyí, mu un kí ó má a lọ, kí ó sì di aya ọmọ olúwa à rẹ, bí Olúwa ti fẹ́.”

52. Nígbà tí ọmọ-ọ̀dọ̀ Ábúráhámù gbọ́ ohun tí wọ́n wí, ó wólẹ̀ níwájú Olúwa.

53. Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rèbékà, ó fún arákùnrin Rèbékà àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú.

54. Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà.Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.”

55. Ṣùgbọ́n arákùnrin Rèbékà àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, “A fẹ́ kí Rèbékà wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn ìyẹn, ìwọ le máa mu lọ.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 24