Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 24:44-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. tí ó bá sì wí fún mi pé, “Mu ún, èmi yóò sì tún pọn omi fún àwọn ràkunmí rẹ pẹ̀lú,” Jẹ́ kí ẹni náà jẹ́ ẹni tí Olúwa yàn fún ọmọ Ábúráhámù, olúwa mi.’

45. “Kí n sì tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rèbékà jáde wá pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀, ó sì lọ sí ibi ìsun omi ó sì pọn omi. Mo sì wí fun un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi ni omi mu.’

46. “Kíákíá ni ó sọ ìkòkò rẹ̀ kalẹ̀ láti èjìká rẹ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mu ún, èmi yóò sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹ̀lú.’ Mo sì mu, ó sì tún fún àwọn ràkúnmí mi mu pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 24