Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 24:34-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Nítorí náà ó wí pé, “Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni èmi.

35. Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún-un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin àti ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

36. Ṣárà aya olúwa mi sì ti bí ọmọkùnrin kan fún un, ní ìgbà ogbó rẹ̀, olúwa mi sì ti fún ọmọ náà ní ohun gbogbo tí ó ní.

37. Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrin àwọn ọmọbìnrin Kénánì, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé,

38. Ṣùgbọ́n lọ sí ìdílé baba mi láàrin àwọn ìbátan mi kí o sì fẹ́ aya fún ọmọ mi.’

39. “Mo sì bí olúwa mi léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà kò bá fẹ́ bá mi wá ńkọ́?’

40. “Ó sì dáhùn wí pé, ‘Olúwa, níwájú ẹni tí èmi ń rìn yóò rán Ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ yóò sì jẹ́ kí o ṣe aṣeyọrí ní ìrìn-àjò rẹ, kí ìwọ kí ó ba le fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrin àwọn ìbátan mi, àti láàrin àwọn ìdílé baba mi.

41. Nígbà tí ìwọ bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé baba mi (gẹ́gẹ́ bí mo tí wí), nígbà náà ni ìwọ tó bọ́ nínú ìbúra yìí.’

42. “Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa mi, bí ìwọ bá fẹ́, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ṣe àṣeyọ́rí lórí ohun tí mo bá wá yìí,

43. Wò ó, mo dúró ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi yìí, kí ó ṣe pé, nígbà tí wúndíá kan bá jáde wá pọn omi, tí èmi sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ìwọ̀nba omi díẹ̀ mu nínú ládugbó rẹ”,

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 24