Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 24:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘mu un, èmi ó sì fún àwọn ràkunmí rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Ísáákì. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.”

15. Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rèbékà dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Bétúélì ni. Bétúélì yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù.

16. Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúndíá ni, kò sì tíì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi.

17. Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé e rẹ̀ ó sì wí fun un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ.”

18. Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún-un mu.

19. Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ràkunmí rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.”

20. Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ síbi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ràkunmí, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn.

21. Láì sọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínnífínní láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run ti ṣe ìrìn-àjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

22. Lẹ́yìn tí àwọn ràkunmí náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọn sékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n sékélì wúrà mẹ́wàá.

23. Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe? Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?”

24. Ó dáhùn pé, “Bétúélì ọmọ tí Mílíkà bí fún Náhórì ni baba mi”

25. Ó sì fi kún un pé, “A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ koríko àti oúnjẹ fún àwọn ràkunmí yín àti yàrá pẹ̀lú fún-un yín láti wọ̀ sí.”

26. Nígbà náà ni ọkùnrin náà tẹríba, ó sì sin Olúwa.

27. Wí pe, “Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa mi ti kò jẹ́ kí àánú àti òtítọ́ rẹ̀ kí ó yẹ̀ lọ́dọ̀ olúwa mi. Ní ti èmi Olúwa ti darí ìrìn-àjò mi sí ilé ìbátan olúwa mi.”

28. Ọmọbìnrin náà sì sáré, ó sì lọ sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀.

29. Rèbékà ní arákùnrin tí ń jẹ́ Lábánì; Lábánì sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 24