Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 21:22-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ní àkókò yìí ni ọba Ábímélékì àti Píkólì, olórí ogun rẹ̀ wí fún Ábúráhámù pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.

23. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fi hàn fún ọ pẹ̀lú.”

24. Ábúráhámù sì wí pé, “Èmí búra.”

25. Nígbà náà ni Ábúráhámù fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Ábímélékì nípa kànga tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n Ábímélékì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe èyí, ìwọ kò sì sọ fún mi tẹ́lẹ̀, òní ni mo sẹ̀sẹ̀ ń gbọ́ báyìí.”

27. Ábúráhámù sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Ábímélékì. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú.

28. Ábúráhámù sì ya abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀.

29. Ábímélékì sì béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”

30. Ó da lóhùn pé “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”

31. Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Baa-Ṣébà nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra.

32. Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Báá-Ṣébà yìí ni Ábímélékì àti Píkólì olórí ogun rẹ̀ pada sí ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì.

33. Ábúráhámù sì gbin igi Támárísíkì kan sí Báá-Ṣébà, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé.

34. Ábúráhámù sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì fún ọjọ́ pípẹ́.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 21