Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 2:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀.

7. Olúwa Ọlọ́run sì mọ ènìyàn láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀, ó si mí èémí sí ihò imú rẹ̀, èémí ìyè, ènìyàn sì di ẹ̀dá alààyè.

8. Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì ní ìhà ìlà oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.

9. Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn-ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárin ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.

10. Odò kan sì ń ti Édẹ́nì sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin.

11. Orúkọ èkínní ni Písónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà gbé wà.

12. (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjíá àti òkúta oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).

13. Orúkọ odò kejì ni Gíhónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kúsì ká.

14. Orúkọ odò kẹta ni Tígírísì: òun ni ó sàn ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Áṣúrì. Odò kẹ́rin ni Yúfúrátè.

15. Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

16. Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “ìwọ́ lè jẹ lára èyíkéyìí èṣo àwọn igi inú ọgbà;

17. ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èṣo igi ìmọ̀ rere àti èṣo igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kú.”

18. Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”

19. Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 2