Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 19:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n Lọ́tì rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe oúnjẹ fún wọn, ó ṣe Búrẹ́dì aláìwú wọ́n sì jẹ ẹ́.

4. Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Ṣódómù tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká.

5. Wọ́n pe Lọ́tì pé, “Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ńkọ́? Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.”

6. Lọ́tì sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde.

7. Ó sì wí pé; “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe se ohun búburú yìí,

8. kíyèsí i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.”

9. Wọ́n sì wí fún Lọ́tì pé “Yàgò lọ́nà fún wa, o jẹ́ àlejò láàrin wa, o wá ń fẹ́ ṣe onídájọ́: ohun tí a ó fi ṣe ọ́ ju ohun tí a ó fi ṣe wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọ́tì, wọ́n sì súnmọ ọn láti fọ́ ilẹ̀kùn.

10. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọ́tì wọlé, wọ́n sì ti ilẹ̀kùn.

11. Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà: wọ́n kò sì rí ẹnu ọ̀nà mọ́.

12. Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọ́tì pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ̀ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí,

13. nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búrurú wọn ń dí púpọ̀ níwájú Olúwa, Olúwa sì rán wa láti pa á run.”

14. Nígbà náà ni Lọ́tì jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí nítorí Olúwa fẹ́ pa ilu yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe.

15. Ní àfẹ̀mọ́jú, àwọn ańgẹ́lì náà rọ Lọ́tì pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìnín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 19