Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 19:27-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa.

28. Ó sì wo ìhà Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru.

29. Ọlọ́run sì rántí Ábúráhámù, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọ́tì jáde kúrò láàrin ìparun náà, tí ó kọ lu ìlú tí Lọ́tì ti gbé.

30. Lọ́tì àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò-àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Sóárì.

31. Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbégbé yìí tí ì bá bá wa lò pọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé.

32. Wá, jẹ́ kí a mú bàbá wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lò pọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.”

33. Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lò pọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìdè.

34. Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti bàbá mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.”

35. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé ṣùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde.

36. Àwọn ọmọbìnrin Lọ́tì méjèèjì sì lóyún fún baba wọn.

37. Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù. Òun ni baba ńlá àwọn ará Móábù lónìí.

38. Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-Ámì. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ámónì lónìí.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 19