Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 19:22-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Tètè! Sá lọ ṣíbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀,” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Ṣóárì).

23. Nígbà tí Lọ́tì yóò fi dé ìlú náà oòrùn ti yọ.

24. Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti Ṣúlúfúrù (òkúta iná) ṣórí Ṣódómù àti Gòmórà-láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá.

25. Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n aya Lọ́tì bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di òpó (ọ̀wọ́n) iyọ̀.

27. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa.

28. Ó sì wo ìhà Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru.

29. Ọlọ́run sì rántí Ábúráhámù, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọ́tì jáde kúrò láàrin ìparun náà, tí ó kọ lu ìlú tí Lọ́tì ti gbé.

30. Lọ́tì àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò-àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Sóárì.

31. Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbégbé yìí tí ì bá bá wa lò pọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé.

32. Wá, jẹ́ kí a mú bàbá wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lò pọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.”

33. Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lò pọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìdè.

34. Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti bàbá mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.”

35. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé ṣùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde.

36. Àwọn ọmọbìnrin Lọ́tì méjèèjì sì lóyún fún baba wọn.

37. Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù. Òun ni baba ńlá àwọn ará Móábù lónìí.

38. Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-Ámì. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ámónì lónìí.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 19