Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 19:12-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọ́tì pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ̀ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí,

13. nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búrurú wọn ń dí púpọ̀ níwájú Olúwa, Olúwa sì rán wa láti pa á run.”

14. Nígbà náà ni Lọ́tì jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí nítorí Olúwa fẹ́ pa ilu yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe.

15. Ní àfẹ̀mọ́jú, àwọn ańgẹ́lì náà rọ Lọ́tì pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìnín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

16. Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí Olúwa sàánú fún wọn.

17. Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde tán, ọ̀kan nínú àwọn Ańgẹ́lì náà wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí ti yín, ẹ má ṣe wẹ̀yìn, orí òkè ni kí ẹ sá lọ, ẹ má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣègbé!”

18. Ṣùgbọ́n Lọ́tì wí fún wọn pé, “Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́!

19. Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí oju rere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, Èmi kò le è ṣá lọ sórí òkè, kí búrurú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú.

20. Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòòsí láti ṣá sí: jẹ́ kí n ṣá lọ ṣíbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́?, Ẹ̀mí mi yóò sì yè.”

21. Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀.

22. Tètè! Sá lọ ṣíbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀,” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Ṣóárì).

23. Nígbà tí Lọ́tì yóò fi dé ìlú náà oòrùn ti yọ.

24. Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti Ṣúlúfúrù (òkúta iná) ṣórí Ṣódómù àti Gòmórà-láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá.

25. Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n aya Lọ́tì bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di òpó (ọ̀wọ́n) iyọ̀.

27. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa.

28. Ó sì wo ìhà Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru.

29. Ọlọ́run sì rántí Ábúráhámù, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọ́tì jáde kúrò láàrin ìparun náà, tí ó kọ lu ìlú tí Lọ́tì ti gbé.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 19