Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 19:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àsáálẹ́, àwọn ańgẹ́lì méjì sì wá sí ìlú Ṣódómù, Lọ́tì sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dide láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sí foríbalẹ̀ fún wọn.

2. Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.”Wọ́n sì wí pé, “Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní.”

3. Ṣùgbọ́n Lọ́tì rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe oúnjẹ fún wọn, ó ṣe Búrẹ́dì aláìwú wọ́n sì jẹ ẹ́.

4. Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Ṣódómù tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká.

5. Wọ́n pe Lọ́tì pé, “Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ńkọ́? Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.”

6. Lọ́tì sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde.

7. Ó sì wí pé; “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe se ohun búburú yìí,

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 19