Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 18:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ jẹ́ kí a bu omi díẹ̀ wá kí ẹ̀yin kí ó wẹ ẹṣẹ̀ yín, kí ẹ sì sinmi lábẹ́ igi níhìn-ín.

5. Ẹ jẹ́ kí n wá oúnjẹ wá fún-un yín kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ, kí ara sì tù yín, kí ẹ si tẹ̀ṣíwájú ní ọ̀nà yín, nígbà tí ẹ ti yà ní ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín.”Wọn sì wí pé “Ó dára.”

6. Ábúráhámù sì yára tọ Ṣárà aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òṣùwọn ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.”

7. Ó sì tún sáré lọ sí ibi agbo ẹran, ó sì mú ọmọ màlúù kan fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì tètè ṣè é.

8. Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé e ṣíwájú wọn. Ó sì dúró nítòòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́.

9. Wọn bèèrè pé, “Ṣárà aya rẹ ńkọ́?”Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.”

10. Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Ṣárà aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.”Sárà sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn wọn.

11. Ábúráhámù àti Ṣárà sì ti di arúgbó: Ṣárà sì ti kọjá àsìkò ìbímọ.

12. Nítorí náà, Ṣárà rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?”

13. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Ábúráhámù pé, “Kín ló dé tí Ṣárà fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tan?’

14. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó sòro jù fún Olúwa? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Ṣárà yóò si bí ọmọkùnrin.”

15. Ẹ̀rù sì ba Ṣárà, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín.Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún-un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rín-ín.”

16. Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Ṣódómù, Ábúráhámù sì sìn wọ́n dé ọ̀nà.

17. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Ábúráhámù bí?

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 18