Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 16:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ańgẹ́lì Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.”

10. Ańgẹ́lì náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.”

11. Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé,“Ìwọ ti lóyún ìwọ yóò sì bíọmọkùnrin kan,ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáélì,nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ.

12. Òun yóò jẹ́ ẹhànnà ènìyànyóò máa tako gbogbo ènìyàn,gbogbo ènìyàn yóò sì máa takò ó,kì yóò sì bá awọn arákùnrin rẹ̀gbé ní ìrẹ́pọ̀.”

13. Ó sì fi pe Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.”

14. Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Róì: kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà lágbedeméjì Kédásì àti Bérédì.

15. Ágárì sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísímáélì.

16. Ábúrámù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndín-láàádọ́rùn-ún (86) nígbà tí Hágárì bí Ísímáélì fún-un.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 16