Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 15:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “Olúwa, alágbára, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Élíásérì ará Dámásíkù ni yóò sì jogún mi,”

3. Ábúrámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé è mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

4. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé (ajogún) rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.”

5. Olúwa sì mú Ábúrámù jáde síta ó sì wí fún un pé, “Gbójú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀-bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú ọmọ rẹ yóò rí.”

6. Ábúrámù sì gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sì òdodo fun-un.

7. Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Úrì ti Kálídéà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”

8. Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “Olúwa Ọlọ́run, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”

9. Nítorí náà, Olúwa wí fún-un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́tamẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 15