Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 15:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Bí oòrùn ti ń wọ̀, Ábúrámù sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó.

13. Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Mọ èyí dájú pé, àwọn ìran rẹ yóò ṣe àtìpó ní orílẹ̀ èdè tí kì í ṣe ti wọn, a ó kó wọn lẹ́rú, a ó sì jẹ wọ́n ní ìyà fún irínwó ọdún (400).

14. Ṣùgbọ́n èmi yóò dá orílẹ̀ èdè náà tí wọn yóò sìn lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀.

15. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin.

16. Ní ìran kẹ́rin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Ámórì kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”

17. Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì sú, ìkòkò iná tí ń sèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrin ẹ̀là a ẹran náà.

18. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábúrámù, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Éjíbítì dé odò ńlá Yúfúrátè:

19. ilẹ̀ àwọn ará Kénì, Kádímónì,

20. Ítì, Pérísísì, Réfáímù.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 15