15. Nígbà tí àwọn ìjòyè Fáráò sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú u Fáráò, Wọ́n sì mú un lọ sí ààfin,
16. Ó sì kẹ́ Ábúrámù dáradára nítorí Ṣáráì, Ábúrámù sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú u ràkunmí.
17. Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-àrùn búburú sí Fáráò àti ilé rẹ̀, nítorí Sáráì aya Ábúrámù.
18. Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Ábúrámù, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí n ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe?
19. Èéṣe tí o fi wí pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya? Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí sì o máa lọ.”
20. Nígbà náà ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Ábúrámù, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.