Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 12:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì wí fún Ábúrámù, “Jáde kúrò ní ile rẹ àti lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ àti kúrò ní ìdílé baba rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi ó fi hàn ọ́.

2. “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńláÈmi yóò sì bùkún fún ọ.Èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá,ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí.

3. Àwọn tí ó súre fún ọ ni Èmi yóò súre fún,ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré;Nípaṣẹ̀ rẹ ni a ó sì bùkúngbogbo ènìyàn ayé”

4. Bẹ́ẹ̀ ni Ábúrámù lọ bí Olúwa ti sọ fún un. Lọ́tì náà sì bá a lọ. Ábúrámù jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin (75) ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Háránì.

5. Ábúrámù sì mú Ṣáráì aya rẹ̀, àti Lọ́tì ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kó jọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Háránì. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kénánì. Wọ́n sì gúnlẹ̀ ṣíbẹ̀.

6. Ábúrámù sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni Móórè ní Ṣékémù. Àwọn ará Kénánì sì wà ní ilẹ̀ náà.

7. Olúwa sì farahan Ábúrámù, ó sì wí fún un pé, “Ìran rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Ábúrámù tẹ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀ fún Olúwa tí ó fara hàn-án.

8. Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì, ó sì pàgọ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀. Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀ oòrùn, Háì wà ní ìlà oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 12