Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 11:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbérò tí wọn kò ní le ṣeyọrí.

7. Ẹ̀ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má baà yé ara wọn mọ́.”

8. Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó.

9. Ìdí èyí ni a fi pè é ní Bábílónì nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.

10. Wọ̀nyí ni ìran ṢémùỌdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣémù pé ọgọ́rùn-ún ọdún (100) ni ó bí Áfákísádì.

11. Lẹ́yìn tí ó bí Áfákísádì, ó tún wà láàyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

12. Nígbà tí Áfákísádì pé ọdún marùndínlógójì (35) ni ó bí Ṣélà.

13. Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírínwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣélà, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

14. Nígbà tí Ṣélà pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Ébérì.

15. Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ébérì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

16. Ébérì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pélégì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 11