Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 11:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ó tún wà láàyè lẹ́yìn tí ó bí Ṣérúgì fún igba-ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

22. Nígbà tí Ṣérúgì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Náhórì.

23. Ó sì wà láàyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Náhórì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

24. Nígbà tí Náhórì pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹ́rà.

25. Ó sì wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹ́rà, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

26. Lẹ́yìn tí Tẹ́rà pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì.

27. Wọ̀nyí ni ìran Tẹ́rà: Tẹ́rà ni baba Ábúrámù, Náhórì àti Áránì, Áránì sì bí Lọ́tì.

28. Áránì sì kú ṣáájú Tẹ́rà baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Úrì ti ilẹ̀ Kálídéà.

29. Ábúrámù àti Náhórì sì gbéyàwó. Orúkọ aya Ábúrámù ni Sáráì, nígbà tí aya Náhórì ń jẹ́ Mílíkà, tí ṣe ọmọ Áránì. Áránì ni ó bí Mílíkà àti Ísíkà.

30. Sáráì sì yàgàn, kò sì bímọ.

31. Tẹ́rà sì mú ọmọ rẹ̀ Ábúrámù àti Lọ́tì ọmọ Áránì, ọmọ-ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sáráì tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Ábúrámù pẹ̀lú, gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Úrì ti Kálídéà láti lọ sí ilẹ̀ Kénánì. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Áránì wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.

32. Nígbà tí Tẹ́rà pé ọmọ igba ó lé márùn-ún ọdún (205) ni ó kú nì Áránì

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 11