Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo.

2. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀ṣíwájú lọ sí ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Sínárì (Bábílónì), wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀.

3. Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sun wọ́n jiná.” Bíríkì ni wọn ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọn fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).

4. Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé-ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí á baà lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

5. Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé-ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́.

6. Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbérò tí wọn kò ní le ṣeyọrí.

7. Ẹ̀ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má baà yé ara wọn mọ́.”

8. Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó.

9. Ìdí èyí ni a fi pè é ní Bábílónì nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 11