Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 10:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ìran àwọn ọmọ Nóà: Ṣémù, Ámù àti Jáfétì, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.

2. Àwọn ọmọ Jáfétì ni:Gómérì, Mágógì, Mádáì, Jáfánì, Túbálì, Méṣékì àti Tírásì.

3. Àwọn ọmọ Gómérì ni:Áṣíkénásì, Rífátì àti Tógárímà.

4. Àwọn ọmọ Jáfánì ni:Élíṣà, Tásísì, Kítímù, àti Ródánímù.

5. (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbégbé tí omi wà ti tàn ká agbégbé wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀ èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).

6. Àwọn ọmọ Ámù ni:Kúsì, Mísíráímù, Fútì àti Kénánì.

7. Àwọn ọmọ Kúsì ni:Ṣébà, Háfílà, Ṣábátà, Rámà, àti Ṣábítékà.Àwọn ọmọ Rámà ni:Ṣébà àti Dédánì.

8. Kúsì sì bí Nímúrọ́dù, èyí tí ó di alágbára àti jagunjagun ní ayé.

9. Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nímúrọ́dù-ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”

10. Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Bábílónì, Érékì, Ákádì, Kálínéhì, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣínárì.

11. Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí dé Áṣíríà, níbi tí ó ti tẹ ìlú Nínéfè, Réhóbótì àti Kálà,

12. àti Résínì, tí ó wà ní àárin Nínéfè àti Kálà, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.

13. Mísíráímù ni baba ńlá àwọn aráLúdì, Ánámì, Léhábì, Náfítúhímù.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 10