Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 1:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárin ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.

19. Àsálẹ́ àti òwúrọ jẹ́ ọjọ́ kẹrin.

20. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfuurufú.”

21. Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá-ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.

22. Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.”

23. Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kárùn-ún.

24. Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

25. Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.

26. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ohun ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.”

27. Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a;akọ àti abo ni ó dá wọn.

28. Ọlọ́run sì súre fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.”

29. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ọgbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín.

30. Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà: gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

31. Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àsálẹ́ àti òwúrọ̀, ó jẹ́ ọjọ́ kẹfà.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 1