Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 47:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Ní ìhà ìlà oòrùn ààlà yóò wá sí àárin Háúránù àti Dámásíkù, lọ sí apá Jọ́dánì láàárin Gílíádì àti ilẹ̀ oòrùn àti títí dé Támárì. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà oòrùn.

19. “Ní ìhà gúsù yóò lọ láti Támérì títí dé ibi omi méríba Kádési, lẹ́yìn náà ni ìhà wádìí tí Éjíbítì lọ sí òkun ńlá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà gúsù.

20. “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hámátì. Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀ oòrùn.

21. “Ìwọ ní láti pin ilẹ̀ yìí ní àárin ara yín gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

22. Ìwọ yóò pín gẹ́gẹ́ bí ìní fún ara yín àti fún àwọn àjòjì tí ó ń gbé ní àárin yín tí ó sì ní àwọn ọmọ. Ìwọ yóò sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ àwọn ará Ísírẹ́lì; papọ̀ mọ́ yin ni kí a pín ìní fún wọn ní àárin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

23. Ní àárin ẹ̀yàkẹyà tí àwọn àlejò ń gbé; wọn gbọdọ̀ fi ìní tirẹ̀ fún-ún,” ní Olúwa Ọba pa lásẹ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 47