Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 46:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmí ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.

5. Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú éfà kọ̀ọ̀kan.

6. Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n.

7. Yóò si pèsè ọrẹ-ẹbọ jíjẹ éfà fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti éfà kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún éfà kan.

8. Nígbà tí ọmọ aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.

9. “ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá ṣíwájú Olúwa ni àwọn àjọ tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gba tí ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé padà, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.

10. Ọmọ aládé gbọdọ̀ wà ní àárin wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.

11. “ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan pẹ̀lú àgbò kan, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá se wu onílúlùkù, Pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan.

12. Nígbà tí ọmọ aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí ó wà ni sísí sílẹ̀ fún-un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, oun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu ọ̀nà.

13. “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀.

14. Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú éfà àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.

15. Nítorí náà ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

16. “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba sọ: Tí ọmọ aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tíwọn nípa ogún jíjẹ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 46