Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 41:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ni nínípọn. Agbègbè tí ó wà lófo ní àárin àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo.

10. Yàrá àwọn àlùfáà jẹ́ ogun ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ yí pó témpílì náà.

11. Àwọn ojú ọ̀nà àbáwọlé wá sí àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́, ọ̀kan ní àríwá àti èkejì ní gúsù, ojú ọ̀nà ni ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀wọ́ márùn-ún ní fífẹ̀ yípo rẹ̀.

12. Ilé tí ó dojúkọ ìta gbangba ìṣèré ilé Ọlọ́run náà ní ìhà ìwọ̀ òòrùn jẹ́ àádọ́rin ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀. Ògiri ilé náà nípọn tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

13. Lẹ́yìn èyí ní ó wá wọn ilé Ọlọ́run: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ìta gbangba ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ilé àti ògiri rẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn.

14. Ibú ìta gbangba ilé Ọlọ́run ní ìhà ìlà òòrùn, papọ̀ mọ́ iwájú ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 41