Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 41:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi lọ sí ìta ibi mímọ́, ó sì wọn àwọn àtẹ́rígbà náà; ìbú atẹrígbà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ègbẹ́ kọ̀ọ̀kan.

2. Ẹnu ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ ògiri ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Ó sì wọn ìta ibi mímọ́ bákan náà; ó jẹ́ ogójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀.

3. Lẹ́yìn náà ó lọ sí inú yàrá ibi mímọ́, ó sì wọn àtẹ́rígbà àbáwọlé: ìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni fífẹ̀. Àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ni fífẹ̀.

4. O sì wọn gígùn inú yàrá ibi mímọ́; o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ títí dé ìparí ìta ibi mímọ́. O sì sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi mímọ́ jùlọ.”

5. Lẹ́yìn náà ó wọn ògiri ilé Ọlọ́run náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní nínípọn, yàrá kọ̀ọ̀kan tí ó wà ńi ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.

6. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ wà ni ìpele mẹ́ta, lórí ara wọn, nígbà ọgbọ̀n lórí ìkọ̀ọ̀kan. Àwọn arópòdógìri wà yípo ògiri ilé Ọlọ́run náà mú kí ògiri àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́gbẹ́ náà ní agbára, ni ọ̀nà tí àwọn ìfaratì náà kò fi wọ inú ògiri ilé Ọlọ́run náà lọ.

7. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo tẹ́ḿpìlì ń fẹ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń lọ sí òkè sí i. Àwọn ilé tí a kọ́ yípo ilé Ọlọ́run ni a kọ́ sókè ní pele ní pele, èyí mú kí àwọn yàrá yìí máa fẹ̀ sí i bí ó ṣe ń gòkè sí i. Àtẹ̀gùn rẹ̀ gba ti àwùjọ ilé àárin lọ sókè láti ilé títí dé òkè pátapáta.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 41