Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 38:16-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gógì, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀ èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fí ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.

17. “ ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ìwọ ha kọ́ ni mo ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà ìṣáájú láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi ti Ísírẹ́lì? Ní ìgbà náà wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé èmi yóò mú ọ lòdì sí wọn.

18. Èyí ni ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà: Nígbà tí Gógì bá kọlu ilẹ̀ Ísírẹ́lì, gbígbóná ibínú mi yóò ru sókè, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

19. Ní ìtara mi àti ní gbígbóná ìbínú mi, Mo tẹnumọ́-ọn pé; ní àsìkò náà ilẹ̀ mímì tíi ó lágbára ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì yóò ṣẹlẹ̀.

20. Ẹja inú òkun, àwọn ẹyẹ òfuurufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi. A óò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀.

21. Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gógì ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀.

22. Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀sílẹ̀; Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀.

23. Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 38