Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 31:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Mo fi lé alákóso àwọn orílẹ̀ èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan,

12. àwọn orílẹ̀ èdè àjòjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárin àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìjì rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀.

13. Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó subú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ wà ní àárin ẹ̀ka rẹ̀.

14. Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárin àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.

15. “ ‘Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jínjìn náà; Mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lẹ́bánónì ní aṣọ, gbogbo igi ìgbẹ́ gbẹ dànù.

16. Mo mú kí orílẹ̀ èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìṣàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Édẹ́nì, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lẹ́bánónì, gbogbo igi tí ó ní omi dáadáa ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀.

17. Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ ìjì rẹ̀, àwọn àjòjì rẹ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.

18. “ ‘Èwo lára igi Édẹ́nì ní a lè fi wé ọ ní dídán àti ọlá ńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Édẹ́nì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárin àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.“ ‘Èyí yìí ní Fáráò àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 31