Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 29:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Éjíbítì padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Pátírósì, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.

15. Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹ̀lẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, ti wọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

16. Éjíbítì kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Ísírẹ́lì mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedédé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.’ ”

17. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

18. “Ọmọ ènìyàn, Nebukadinésárì ọba Bábílónì mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tírè. Gbogbo ori pá, àti gbogbo èjìká bó, ṣíbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owo ọ̀yà gbà láti Tírè fún wa, fún ìrú ti a ti sìn.

19. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, Èmi yóò fi Éjíbítì fún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀.

20. Èmi ti fi Éjíbítì fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

21. “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ilé Ísírẹ́lì ní agbára, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárin wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 29