Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 29:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ Éjíbítì di píparun àti ahoro, pátapáta, láti Mígídólì lọ dé Ásíwánì, dé ààlà ilẹ Kúṣì.

11. Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún.

12. Èmi yóò sọ ilẹ Éjíbítì di ọ̀kan ní àárin àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sáàárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárin gbogbo ilẹ̀.

13. “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Éjíbítì jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí.

14. Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Éjíbítì padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Pátírósì, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 29