Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 23:47-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Àwọn ènìyànkénìyàn náà yóò sọ wọ́n ni òkúta, yóò sì gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà wọn; wọn ó sì pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n ó sì jó àwọn ilé wọn kanlẹ̀.

48. “Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ni ilẹ̀ náà, kí gbogbo àwọn obìnrin le gba ìkìlọ̀ kí wọn kí ó ma sì ṣe fara wé ọ.

49. Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá. Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 23