Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 23:42-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. “Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú Sábéánì láti ihà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ èniyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dárádárá sì wà ní orí wọn.

43. Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ ṣá nípa aṣẹ́wó ṣíṣe, ‘Nísìnyí jẹ kí wọn lo o bí aṣẹ́wó, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’

44. Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá aṣẹ́wó sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Óhólà àti Óhólíbà.

45. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin olódodo yóò pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìyà jẹ àwọn obìnrin tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé aṣẹ́wó ni wọ́n ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.

46. “Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Mú àgbájọ àwọn ènìyàn kénìyàn wá sọ́dọ̀ wọn ki ó sì fi wọn lé ọwọ́ ìpayà àti ìkógun.

47. Àwọn ènìyànkénìyàn náà yóò sọ wọ́n ni òkúta, yóò sì gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà wọn; wọn ó sì pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n ó sì jó àwọn ilé wọn kanlẹ̀.

48. “Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ni ilẹ̀ náà, kí gbogbo àwọn obìnrin le gba ìkìlọ̀ kí wọn kí ó ma sì ṣe fara wé ọ.

49. Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá. Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 23