Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 22:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà, yóò fi ọ se ẹlẹ́yà, Áà! ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.

6. “ ‘Wo bí ìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ọba Ísírẹ́lì tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀.

7. Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwà-kúwà sí aláìní baba àti opó.

8. Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkúlò.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 22