Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 22:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn.

3. Kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárin rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère,

4. Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, iparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀ èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú.

5. Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà, yóò fi ọ se ẹlẹ́yà, Áà! ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.

6. “ ‘Wo bí ìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ọba Ísírẹ́lì tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀.

7. Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwà-kúwà sí aláìní baba àti opó.

8. Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkúlò.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 22