Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 20:28-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí láti fún wọn, gbogbo igi ilẹ̀ gíga àti gbogbo igi to rúwé ni wọn tí ń rúbọ wọn ṣe irubọ to ń mú mi bínú, níbẹ̀ sì ni wọn ń ṣe òórùn dídùn wọn, ti wọn sì ń ta ọrẹ ohun mímu sílẹ̀.

29. Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé: Kí ní ibi gíga tí ẹ n lọ yìí?’ ” (Wọn sì ń pè ní Bámà di onì yìí.)

30. “Nítorí náà sọ fún ile Ísírẹ́lì: ‘Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Ṣe o fẹ bara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, to ń ṣe àgbèrè nípa tí tẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra?

31. Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, irúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú wọn la iná kọjá-ẹ ń tèṣíwájú láti bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, èmi ó wa jẹ ki ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi bí ilé Ísírẹ́lì? Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, N kò ní i jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.

32. “ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ dàbí àwọn orílẹ̀ èdè yóòkù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá.

33. Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, ń ó jọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí ń ó nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi.

34. Èmi yóò mú yín jáde láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni.

35. Èmi yóò mú yín wá sí ihà àwọn orílẹ̀ èdè, níbẹ̀ ni ojúkójú ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ lé e yín lórí.

36. Bí mo ṣe ṣe idájọ́ àwọn baba yín nínú ihà nílẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe idájọ́ yín ní Olúwa Ọlọ́run wí.

37. Èmi yóò kíyèsí i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú

38. Èmi yóò ṣa àwọn tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí mí kúrò láàrin yín. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé èmi yóò mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọn ń gbé, síbẹ̀ wọn kò ní dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní Olúwa.

39. “ ‘Ní tí ẹ̀yin, ilé Ísírẹ́lì, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́.

40. Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Ísírẹ́lì, ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò sìn mí; n ó sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ ń ó bèèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín

41. N o tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín ká sí, ń ó sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin yín lójú àwọn orilẹ̀ èdè.

42. Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 20