Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 20:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ kẹ́wàá, oṣù kàrùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbà Ísírẹ́lì wá wádìí lọ́wọ́ Olúwa, wọn jòkòó níwájú mi.

2. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

3. “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbà Ísírẹ́lì, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí. N ò ní í gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 20