Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 19:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọ̀n ìlú wọn di ahoro.Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.

8. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀ èdè tó yìí ká dìde sí i,wọn ta ẹ̀wọ̀n fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.

9. Wọn fi ìkọ́ gbé e sínú ago, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Bábílónì,wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Ísírẹ́lì.

10. “ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi,

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 19