23. Ǹjẹ́ se mo ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa wí, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ tó sì yè?
24. “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́sẹ̀, tó sì tún n ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kò ni i rántí ọ̀kan kan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.
25. “Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ tún sọ pe, ‘Olúwa kò ṣe é da kò tọ́.’ Gbọ́, ilé Ísírẹ́lì: se ọ̀nà mi ni kò tọ́? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà ti yín gan-an ni kò tọ́?
26. Bí ènìyàn rere ba yípadà kúrò nínú ìwà rere rẹ̀, tó sì dẹ́sẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹsẹ tó ti dá.