Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 18:22-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kàá sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè

23. Ǹjẹ́ se mo ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa wí, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ tó sì yè?

24. “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́sẹ̀, tó sì tún n ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kò ni i rántí ọ̀kan kan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.

25. “Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ tún sọ pe, ‘Olúwa kò ṣe é da kò tọ́.’ Gbọ́, ilé Ísírẹ́lì: se ọ̀nà mi ni kò tọ́? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà ti yín gan-an ni kò tọ́?

26. Bí ènìyàn rere ba yípadà kúrò nínú ìwà rere rẹ̀, tó sì dẹ́sẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹsẹ tó ti dá.

27. Ṣùgbọ́n bi ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú tó ti se, tó si ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, yóò gba ẹ̀mi rẹ̀ là.

28. Nítorí pé ó ronu lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó sì yípadà kúrò nínú wọn, nítootọ́ ni yóò yè; kò sí ní i kú

29. Síbẹ̀, ilé Ísírẹ́lì wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò tọ́.’ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí Ilé Ísírẹ́lì? Kì í wa se pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko tọ?

30. “Nítorí náà, ilé Ísírẹ́lì, n ó da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Ọlọ́run wí. Yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ ma ba a jẹ́ ọ̀nà ìsubú yín.

31. Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mi tuntun. Nitori kí ló fi máa kú, ilé Ísírẹ́lì?

32. Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni Olúwa Ọlọ́run wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 18