Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 17:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Ísírẹ́lì.

3. Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ orísìírísìí wa si Lẹ́bánónì o sì mu ẹ̀ka igi Kédàrì tó ga jùlọ

4. O gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, o mu un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn ọlọ́jà.

5. “ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò.

6. Ó dàgbà, ó sì di àjàrà to kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú si i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o di àjàrà ó sì mu ẹ̀ka àti ewe jáde.

7. “ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ Idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ kí ó le fún-un ni omi.

8. Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sí so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’

9. “Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 17