Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 17:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ní wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Ísírẹ́lì.

3. Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ orísìírísìí wa si Lẹ́bánónì o sì mu ẹ̀ka igi Kédàrì tó ga jùlọ

4. O gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, o mu un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn ọlọ́jà.

5. “ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò.

6. Ó dàgbà, ó sì di àjàrà to kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú si i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o di àjàrà ó sì mu ẹ̀ka àti ewe jáde.

7. “ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ Idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ kí ó le fún-un ni omi.

8. Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sí so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 17