Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 12:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’ ”

26. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

27. “Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ó rí, ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’

28. “Nítorí náà sọ fún wọn, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún ṣíwájú mọ́; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 12