Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 12:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn, ò ń gbé láàrin ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́ran ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ran, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.

3. “Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, lọ́san gangan lójú wọn, kúrò láti ibi tí o wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, yóò yé wọn, wọn ó sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

4. Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn lọ́sàn án gangan, nígbà tó bá sì di alẹ́, loju wọn máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe.

5. Dá ògiri lu lójú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde.

6. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká lójú wọn, bo ojú rẹ, kí o má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ lálẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Ísírẹ́lì.”

7. Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi. Mo kẹ́rù mi jáde lọ́sàn án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbẹ́rù mi léjìká nínú òkùnkùn lójú wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 12