Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 11:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojú kọ ìlà oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wá, mo rí Jáásáníà ọmọ Àsúrì àti Pélátíà ọmọ Bénáyà, tí wọ́n jẹ́ aláṣẹ àwọn ènìyàn.

2. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú.

3. Wọ́n ní, ‘kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’.

4. Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 11