Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ọlọ́run rẹ̀. Fi ìpè sí ẹnu rẹ!Ẹyẹ igún wà lórí ilé Olúwanítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.

2. Ísírẹ́lì kígbe pè mí‘Áà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́!’

3. Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀

4. Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ miwọ́n yan ọmọ aládé láì si ìmọ̀ mi nibẹ̀.Wọ́n fi fàdákà àti wúràṣe ère fún ara wọn,kì a ba le ké wọn kúrò.

5. Ọmọ-mààlu rẹ ti ta ọ́ nù ìwọ Ṣamáríà! Ju ère tí o gbẹ́ nùÌbínú mi ń ru sí wọn:yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?

Ka pipe ipin Hósíà 8