Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 5:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹranàti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,wọn kò ní rí i,ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrin wọn.

7. Wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí Olúwawọ́n sì bí àwọn ọmọ àlè.Nísinsìn yìí, ọdún oṣù tuntunwọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú pín wọn.

8. “Fọn fère ní Gíbíà,kí ẹ sì fun ipè ní Rámà.Ẹ pariwó ogun ní Bẹti-Áfélìmáa wárìrì, ìwọ Bẹ́ńjámínì.

9. Éfúráímù yóò di ahoroní ọjọ́ ìbáwíláàrin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lìMo sọ ohun tí ó dájú.

10. Àwọn olórí Júdà dàbí àwọn tí ímáa yí òkúta ààlà kúrò.Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi léwọn lórí bí ìkún omi.

Ka pipe ipin Hósíà 5