Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 5:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Mo mọ ohun gbogbo nípa ÉfúráímùÍsírẹ́lì kò sì pamọ́ fún miÉfúráímù, ní báyìí ó ti di alágbèrèÍsírẹ́lì sì ti díbàjẹ́

4. “Iṣe wọn kò gbà wọ́n láàyèláti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.Ẹ̀mí àgbèrè wà láàrinwọn kò sì mọ Olúwa.

5. Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí lé wọn;Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti Éfúráímù pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Júdà náà sì kọṣẹ̀ pẹ̀lú wọn.

6. Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹranàti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,wọn kò ní rí i,ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrin wọn.

Ka pipe ipin Hósíà 5