Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 5:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!Ẹ fetí sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì!Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!Ìdájọ́ yìí kàn yín:Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní MísípàÀwọ̀n ti a nà sìlẹ̀ lórí Tábórì

2. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyànGbogbo wọn ni èmi ó bá wí,

3. Mo mọ ohun gbogbo nípa ÉfúráímùÍsírẹ́lì kò sì pamọ́ fún miÉfúráímù, ní báyìí ó ti di alágbèrèÍsírẹ́lì sì ti díbàjẹ́

4. “Iṣe wọn kò gbà wọ́n láàyèláti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.Ẹ̀mí àgbèrè wà láàrinwọn kò sì mọ Olúwa.

5. Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí lé wọn;Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti Éfúráímù pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Júdà náà sì kọṣẹ̀ pẹ̀lú wọn.

6. Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹranàti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,wọn kò ní rí i,ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrin wọn.

7. Wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí Olúwawọ́n sì bí àwọn ọmọ àlè.Nísinsìn yìí, ọdún oṣù tuntunwọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú pín wọn.

8. “Fọn fère ní Gíbíà,kí ẹ sì fun ipè ní Rámà.Ẹ pariwó ogun ní Bẹti-Áfélìmáa wárìrì, ìwọ Bẹ́ńjámínì.

Ka pipe ipin Hósíà 5