Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 4:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;Wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwasílẹ̀

11. ‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè,wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù

12. Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igiỌ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn.Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn sìnàwọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.

13. Wọ́n ń rúbọ lórí àwọn òkè ńlá,Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeréLábẹ́ igi óákù, àti igi pópúlárìàti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dáraNítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrèàti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.

14. “Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yínníyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrètàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín,nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrènítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́.Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ilé òrìṣà.Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!

15. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Ísírẹ́lìÌdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Júdà di ẹlẹ́bi.“Ẹ má ṣe lọ sí Gílígálì.Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Bẹti-ÁfénìẸ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láàyè nítòótọ́!’

16. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe agídíbí alágídí ọmọ màlúùBáwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọnbí àgùntàn ní pápá oko tútù?

17. Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀!

18. Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tánwọ́n tún tẹ̀ṣíwájú nínú àgbèrèàwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.

19. Ìjì ni yóò gbá wọn lọ.Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.

Ka pipe ipin Hósíà 4