Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 13:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìúnÈmi yóò farapamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.

8. Béárì igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbàÈmi yóò bá wọn jà bí?Èmi yóò sì fà wọ́n yabí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya.

9. “A ti pa ọ́ run, ìwọ Ísírẹ́lìnítorí pé ìwọ lòdì sí mi ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ.

10. Níbo ni ọba rẹ gbé wà nìsisin yìí kí ó bá à le gbà ọ là?Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà,àwọn tí ẹ sọ pé,‘Fún wa ní ọba àti ọmọ aládé’?

11. Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín lọ́baNinú ìbínú gbígbóná mi, Mo sì mú un kúrò

12. Ẹ̀bi Éfúráímù ni a tí ko jọgbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀

13. Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá aṢùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́nNígbà tí àsìkò tó,ó kọ̀ láti jáde síta láti inú.

Ka pipe ipin Hósíà 13